Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 13:1-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA si sọ fun Mose pe,

2. Rán enia, ki nwọn ki o si ṣe amí ilẹ Kenaani, ti mo fi fun awọn ọmọ Israeli: ọkunrin kan ni ki ẹnyin ki o rán ninu ẹ̀ya awọn baba wọn, ki olukuluku ki o jẹ́ ijoye ninu wọn.

3. Mose si rán wọn lati ijù Parani lọ, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA: gbogbo awọn ọkunrin na jẹ́ olori awọn ọmọ Israeli.

4. Orukọ wọn si ni wọnyi: ninu ẹ̀ya Reubeni, Ṣammua ọmọ Sakuru.

5. Ninu ẹ̀ya Simeoni, Ṣafati ọmọ Hori.

6. Ninu ẹ̀ya Juda, Kalebu ọmọ Jefunne.

7. Ninu ẹ̀ya Issakari, Igali ọmọ Josefu.

8. Ninu ẹ̀ya Efraimu, Oṣea ọmọ Nuni.

9. Ninu ẹ̀ya Benjamini, Palti ọmọ Rafu.

10. Ninu ẹ̀ya Sebuluni, Gaddieli ọmọ Sodi.

11. Ninu ẹ̀ya Josefu, eyinì ni, ninu ẹ̀ya Manasse, Gadi ọmọ Susi.

12. Ninu ẹ̀ya Dani, Ammieli ọmọ Gemalli.

13. Ninu ẹ̀ya Aṣeri, Seturu ọmọ Mikaeli.

14. Ninu ẹ̀ya Naftali, Nabi ọmọ Fofsi.

15. Ninu ẹ̀ya Gaddi, Geueli ọmọ Maki.

Ka pipe ipin Num 13