Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 10:23-36 Yorùbá Bibeli (YCE)

23. Ati olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Manasse ni Gamalieli ọmọ Pedasuri.

24. Ati olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Benjamini ni Abidani ọmọ Gideoni.

25. Ọpágun ibudó awọn ọmọ Dani, ti o kẹhin gbogbo ibudó, si ṣí gẹgẹ bi ogun wọn: olori ogun rẹ̀ si ni Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai.

26. Ati olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Aṣeri ni Pagieli ọmọ Okrani.

27. Ati olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Naftali ni Ahira ọmọ Enani.

28. Bayi ni ìrin awọn ọmọ Israeli gẹgẹ bi ogun wọn; nwọn si ṣí.

29. Mose si wi fun Hobabu, ọmọ Ragueli ara Midiani, ana Mose pe, Awa nṣí lọ si ibi ti OLUWA ti wi pe, Emi o fi i fun nyin: wá ba wa lọ, awa o ṣe ọ li ore: nitoripe OLUWA sọ̀rọ rere nipa Israeli.

30. On si wi fun u pe, Emi ki yio lọ; ṣugbọn emi o pada lọ si ilẹ mi, ati sọdọ ará mi.

31. O si wipe, Máṣe fi wa silẹ, emi bẹ̀ ọ; iwọ sà mọ̀ pe ni ijù li awa dó si, iwọ o si ma ṣe oju fun wa.

32. Yio si ṣe, bi iwọ ba bá wa lọ, yio si ṣe, pe, orekore ti OLUWA ba ṣe fun wa, on na li awa o ṣe fun ọ.

33. Nwọn si ṣí kuro ni òke OLUWA ni ìrin ijọ́ mẹta: apoti majẹmu OLUWA si ṣiwaju wọn ni ìrin ijọ́ mẹta, lati wá ibi isimi fun wọn.

34. Awọsanma OLUWA mbẹ lori wọn li ọsán, nigbati nwọn ba ṣí kuro ninu ibudó.

35. O si ṣe, nigbati apoti ẹrí ba ṣí siwaju, Mose a si wipe, Dide, OLUWA, ki a si tú awọn ọtá rẹ ká; ki awọn ti o korira rẹ ki o si salọ kuro niwaju rẹ.

36. Nigbati o ba si simi, on a wipe, Pada, OLUWA, sọdọ ẹgbẹgbarun awọn enia Israeli.

Ka pipe ipin Num 10