Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 10:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA si sọ fun Mose pe,

2. Iwọ ṣe ipè fadakà meji; iṣẹ́-ọnà lilù ni ki o ṣe wọn: iwọ o si ma fi wọn pè ajọ, iwọ o si ma fi wọn ṣí ibudó.

3. Nigbati nwọn ba fun wọn, ki gbogbo ijọ ki o pé sọdọ rẹ li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ.

4. Bi o ba ṣepe ipè kan ni nwọn fun, nigbana ni ki awọn ijoye, olori ẹgbẹgbẹrun enia Israeli, ki o pejọ sọdọ rẹ.

5. Nigbati ẹnyin ba si fun ipè idagiri, nigbana ni ki awọn ibudó ti o wà ni ìha ìla-õrùn ki o ṣí siwaju.

6. Nigbati ẹnyin ba si fun ipè idagiri nigba keji, nigbana ni ki awọn ibudó ti o wà ni ìha gusù ki o ṣì siwaju: ki nwọn ki o si fun ipè idagiri ṣíṣi wọn.

7. Ṣugbọn nigbati a o ba pè ijọ pọ̀, ki ẹ fun ipè, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ fun ti idagiri.

8. Awọn ọmọ Aaroni, awọn alufa, ni ki o si fun ipè na; ki nwọn ki o si ma ṣe ìlana lailai fun nyin ni iran-iran nyin.

9. Bi ẹnyin ba si lọ si ogun ni ilẹ nyin lọ ipade awọn ọtá ti nni nyin lara, nigbana ni ki ẹnyin ki o fi ipè fun idagiri; a o si ranti nyin niwaju OLUWA Ọlọrun nyin, a o si gbà nyin lọwọ awọn ọtá nyin.

Ka pipe ipin Num 10