Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 1:42-51 Yorùbá Bibeli (YCE)

42. Ti awọn ọmọ Naftali, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun;

43. Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Naftali, o jẹ́ ẹgba mẹrindilọgbọ̀n o le egbeje.

44. Wọnyi li awọn ti a kà, ti Mose ati Aaroni kà, ati awọn olori Israeli, ọkunrin mejila: olukuluku wà fun ile awọn baba rẹ̀.

45. Bẹ̃ni gbogbo awọn ti a kà ninu awọn ọmọ Israeli, nipa ile baba wọn, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun ni Israeli;

46. Ani gbogbo awọn ti a kà o jẹ́ ọgbọ̀n ọkẹ enia o le egbejidilogun din ãdọta.

47. Ṣugbọn awọn ọmọ Lefi gẹgẹ bi ẹ̀ya baba wọn li a kò kà mọ́ wọn.

48. Nitoripe OLUWA ti sọ fun Mose pe,

49. Kìki ẹ̀ya Lefi ni ki iwọ ki o máṣe kà, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe kà iye wọn mọ́ awọn ọmọ Israeli.

50. Ṣugbọn ki iwọ ki o yàn awọn ọmọ Lefi sori agọ́ érí, ati sori gbogbo ohun-èlo rẹ̀, ati sori ohun gbogbo ti iṣe tirẹ̀: awọn ni ki o ma rù agọ́, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀; awọn ni yio si ma ṣe iṣẹ-ìsin rẹ̀, ki nwọn ki o si dó yi agọ́ na ká.

51. Nigbati agọ́ na ba si ṣí siwaju, ki awọn ọmọ Lefi ki o tú u palẹ: nigbati nwọn o ba si pa agọ́ na, awọn ọmọ Lefi ni ki o gbé e duro: alejó ti o ba sunmọtosi, pipa ni.

Ka pipe ipin Num 1