Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 1:2-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Ẹ kaye gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, olukuluku ọkunrin, nipa ori wọn;

3. Lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun ni Israeli, iwọ ati Aaroni ni ki o kaye wọn gẹgẹ bi ogun wọn.

4. Ki ọkunrin kọkan lati inu olukuluku ẹ̀ya ki o si wà pẹlu nyin; ki olukuluku jẹ́ olori ile awọn baba rẹ̀.

5. Wọnyi si li orukọ awọn ọkunrin na ti yio duro pẹlu nyin: ti Reubeni; Elisuri ọmọ Ṣedeuri.

6. Ti Simeoni; Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai.

7. Ti Juda; Naṣoni ọmọ Amminadabu.

8. Ti Issakari; Netaneli ọmọ Suari.

9. Ti Sebuluni; Eliabu ọmọ Heloni.

10. Ti awọn ọmọ Josefu: ti Efraimu; Elliṣama ọmọ Ammihudu: ti Manasse; Gamalieli ọmọ Pedasuru.

11. Ti Benjamini; Abidani ọmọ Gideoni.

12. Ti Dani; Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai.

13. Ti Aṣeri; Pagieli ọmọ Okanri.

14. Ti Gadi; Eliasafu ọmọ Deueli.

15. Ti Naftali; Ahira ọmọ Enani.

16. Wọnyi li awọn ti a yàn ninu ijọ, olori ẹ̀ya awọn baba wọn, awọn olori ẹgbẹgbẹrun ni Israeli.

Ka pipe ipin Num 1