1. OLUWA si sọ fun Mose ni ijù Sinai, ninu agọ́ ajọ, li ọjọ́ kini oṣù keji, li ọdún keji, ti nwọn jade lati ilẹ Egipti wá, wipe,
2. Ẹ kaye gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, olukuluku ọkunrin, nipa ori wọn;
3. Lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun ni Israeli, iwọ ati Aaroni ni ki o kaye wọn gẹgẹ bi ogun wọn.
4. Ki ọkunrin kọkan lati inu olukuluku ẹ̀ya ki o si wà pẹlu nyin; ki olukuluku jẹ́ olori ile awọn baba rẹ̀.
5. Wọnyi si li orukọ awọn ọkunrin na ti yio duro pẹlu nyin: ti Reubeni; Elisuri ọmọ Ṣedeuri.
6. Ti Simeoni; Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai.
7. Ti Juda; Naṣoni ọmọ Amminadabu.
8. Ti Issakari; Netaneli ọmọ Suari.
9. Ti Sebuluni; Eliabu ọmọ Heloni.
10. Ti awọn ọmọ Josefu: ti Efraimu; Elliṣama ọmọ Ammihudu: ti Manasse; Gamalieli ọmọ Pedasuru.