Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Neh 7:51-64 Yorùbá Bibeli (YCE)

51. Awọn ọmọ Gassamu, awọn ọmọ Ussa, awọn ọmọ Fasea,

52. Awọn ọmọ Besai, awọn ọmọ Meunimu, awọn ọmọ Nefiṣesimu,

53. Awọn ọmọ Bakbuku, awọn ọmọ Hakufa, awọn ọmọ Harhuri,

54. Awọn ọmọ Basliti, awọn ọmọ Mehida, awọn ọmọ Harsa,

55. Awọn ọmọ Barkosi, awọn ọmọ Sisera, awọn ọmọ Tama,

56. Awọn ọmọ Nesia, awọn ọmọ Hatifa.

57. Awọn ọmọ awọn iranṣẹ Solomoni: awọn ọmọ Sotai, awọn ọmọ Sofereti, awọn ọmọ Perida,

58. Awọn ọmọ Jaala, awọn ọmọ Darkoni, awọn ọmọ Giddeli,

59. Awọn ọmọ Ṣefatiah, awọn ọmọ Hattili, awọn ọmọ Pokereti ti Sebaimu, awọn ọmọ Amoni.

60. Gbogbo awọn Netinimu, ati awọn ọmọ awọn iranṣẹ Solomoni jẹ irinwo din mẹjọ.

61. Awọn wọnyi li o si goke lati Telhariṣa, Kerubu, Addoni, ati Immeri wá: ṣugbọn nwọn kò le fi ile baba wọn hàn, tabi iran wọn, bi nwọn iṣe ti Israeli.

62. Awọn ọmọ Delaiah, awọn ọmọ Tobiah, awọn ọmọ Nekoda, ojilelẹgbẹta ole meji.

63. Ati ninu awọn alufa: awọn ọmọ Habaiah, awọn ọmọ Kosi, awọn ọmọ Barsillai, ti o ni ọkan ninu awọn ọmọbinrin Barsillai, ara Gileadi, li aya, a si npè e nipa orukọ wọn.

64. Awọn wọnyi wá iwe orukọ wọn ninu awọn wọnyi ti a kọ orukọ wọn nipa idile ṣugbọn a kò ri i: nitorina li a ṣe yà wọn kurò ninu oyè alufa.

Ka pipe ipin Neh 7