Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Neh 7:1-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O SI ṣe, nigbati a mọ odi na tan, ti mo si gbe ilẹkùn ro, ti a si yan awọn oludena ati awọn akọrin, ati awọn ọmọ Lefi,

2. Mo si fun Hanani arakunrin mi, ati Hananiah ijòye ãfin, li aṣẹ lori Jerusalemu: nitori olododo enia li o ṣe, o si bẹ̀ru Ọlọrun jù enia pupọ lọ.

3. Mo si wi fun wọn pe, Ẹ má jẹ ki ilẹkùn odi Jerusalemu ṣi titi õrùn o fi mú; bi nwọn si ti duro, jẹ ki wọn se ilẹkùn, ki nwọn si há wọn, ki nwọn si yan ẹ̀ṣọ ninu awọn ti ngbe Jerusalemu, olukuluku ninu iṣọ rẹ̀, ati olukuluku ninu ile rẹ̀.

4. Ṣugbọn ilu na gbõrò, o si tobi, awọn enia inu rẹ̀ si kere, a kò si kọ́ ile tan.

5. Ọlọrun mi si fi si mi li ọkàn lati ko awọn ijòye jọ, ati awọn olori, ati awọn enia, ki a le kà wọn nipa idile wọn. Mo si ri iwe idile awọn ti o kọ́ goke wá, mo ri pe, a kọ ọ sinu rẹ̀.

6. Wọnyi ni awọn ọmọ igberiko, ti o gòke wá lati ìgbekun ninu awọn ti a ti ko lọ, ti Nebukadnesari ọba Babiloni ti ko lọ, ti nwọn tun padà wá si Jerusalemu, ati si Juda, olukuluku si ilu rẹ̀.

7. Awọn ti o ba Serubbabeli wá, Jeṣua, Nehemia, Asariah, Raamiah, Nahamani, Mordikai, Bilṣani, Mispereti, Bigfai, Nehumu, Baana. Iye awọn ọkunrin enia Israeli li eyi;

8. Awọn ọmọ Paroṣi, ẹgbã o le mejilelãdọsan.

9. Awọn ọmọ Ṣefatiah, ojidinirinwo o le mejila.

10. Awọn ọmọ Ara, adọtalelẹgbẹta o le meji.

11. Awọn ọmọ Pahat-moabu, ti awọn ọmọ Jeṣua, ati Joabu, ẹgbẹrinla o le mejidilogun.

12. Awọn ọmọ Elamu, ẹgbẹfa o le mẹrinlelãdọta.

13. Awọn ọmọ Sattu, ojilelẹgbẹrin o le marun.

14. Awọn ọmọ Sakkai, ojidilẹgbẹrin.

Ka pipe ipin Neh 7