Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Neh 1:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ọ̀RỌ Nehemiah ọmọ Hakaliah. O si ṣe ninu oṣu Kisleu, ni ogún ọdun, nigba tí mo wà ni Ṣuṣani ãfin.

2. Ni Hanani, ọkan ninu awọn arakunrin mi, on ati awọn ọkunrin kan lati Juda wá sọdọ mi; mo si bi wọn lere niti awọn ara Juda ti o salà, ti o kù ninu awọn igbekùn, ati niti Jerusalemu.

3. Nwọn si wi fun mi pe, Awọn iyokù, ti a fi silẹ nibẹ ninu awọn igbekùn ni igberiko, mbẹ ninu wahala nla ati ẹ̀gan; odi Jerusalemu si wó lulẹ̀, a si fi ilẹkùn rẹ̀ joná.

4. O si ṣe nigbati mo gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, mo joko, mo si sọkun, mo si ṣọ̀fọ ni iye ọjọ, mo si gbãwẹ, mo si gbàdura niwaju Ọlọrun ọrun.

5. Mo si wipe, Emi mbẹ̀bẹ lọdọ rẹ, Oluwa Ọlọrun ọrun, ti o tobi, ti o si li ẹ̀ru, ti npa majẹmu ati ãnu mọ fun awọn ti o fẹ ẹ, ti nwọn si pa ofin rẹ̀ mọ:

6. Tẹ́ eti rẹ silẹ̀ nisisiyi, ki o si ṣi oju rẹ, ki iwọ ba le gbọ́ adura iranṣẹ rẹ, ti mo ngbà niwaju rẹ nisisiyi, tọsan toru fun awọn ọmọ Israeli iranṣẹ rẹ, ti mo si jẹwọ ẹ̀ṣẹ awọn ọmọ Israeli ti a ti ṣẹ̀ si ọ: ati emi ati ile baba mi ti ṣẹ̀.

7. Awa ti huwa ibàjẹ si ọ, awa kò si pa ofin ati ilana ati idajọ mọ, ti iwọ pa li aṣẹ fun Mose iranṣẹ rẹ.

8. Emi bẹ̀ ọ, ranti ọ̀rọ ti iwọ pa laṣẹ fun Mose iranṣẹ rẹ, wipe, Bi ẹnyin ba ṣẹ̀, emi o tú nyin kakiri sãrin awọn orilẹ-ède:

Ka pipe ipin Neh 1