Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nah 2:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ATUNIKA de iwaju rẹ (Ninefe): pa ile-iṣọ mọ, ṣọ ọ̀na na, di àmurè ẹ̀gbẹ rẹ ko le, mura girigiri.

2. Nitori Oluwa tun pada si ọlanla Jakobu, gẹgẹ bi ọlanla Israeli: atunidanù ti tú wọn danù, nwọn si ba ẹka àjara wọn jẹ.

3. A sọ asà awọn ọkunrin alagbara rẹ̀ di pupa, awọn akin wọn wọ̀ odòdó: kẹkẹ́ ogun yio ma kọ bi iná li ọjọ ipèse rẹ̀, igi firi li a o si mì tìti.

4. Ariwo kẹkẹ́ ni igboro, nwọn o si ma gbún ara wọn ni ọ̀na gbigbòro, nwọn o dabi etùfu, nwọn o kọ́ bi mànamána.

5. On o ṣe aṣàro awọn ọlọla rẹ̀: nwọn o kọsẹ̀ ni irìn wọn; nwọn o yara si ibi odi rẹ̀, a o si pèse ãbo rẹ̀.

6. A o ṣi ilẹ̀kun odò wọnni silẹ, a o si sọ ãfin na di yiyọ́.

7. Eyi ti a ti fi idi rẹ̀ mulẹ li a o si dì ni igbèkun lọ, a o si mu u goke wá, ati awọn iranṣẹbinrin rẹ̀ yio fi ohùn bi ti oriri ṣe amọ̀na rẹ̀, nwọn a ma lù aiya wọn.

Ka pipe ipin Nah 2