Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mik 6:10-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Iṣura ìwa buburu ha wà ni ile enia buburu sibẹ̀, ati òṣuwọ̀n aikún ti o jẹ ohun ibinú?

11. Ki emi ha kà wọn si mimọ́ pẹlu òṣuwọ̀n buburu, ati pẹlu àpo òṣuwọ̀n ẹ̀tan?

12. Ti awọn ọlọrọ̀ rẹ̀ kún fun ìwa-ipá, ati awọn ti ngbe inu rẹ̀ ti sọ̀rọ eké, ahọn wọn si kún fun ẹ̀tan li ẹnu wọn.

13. Nitorina pẹlu li emi o ṣe mu ọ ṣàisan ni lilù ọ, ni sisọ ọ dahoro nitori ẹ̀ṣẹ rẹ.

14. Iwọ o jẹun, ṣugbọn iwọ kì yio yo; idábẹ yio wà lãrin rẹ; iwọ o kó kuro, ṣugbọn iwọ kì o lọ lailewu; ati eyi ti o kó lọ li emi o fi fun idà.

15. Iwọ o gbìn, ṣugbọn iwọ kì yio ká; iwọ o tẹ̀ igi olifi, ṣugbọn iwọ kì o fi ororo kunra; ati eso àjara, sugbọn iwọ kì o mu ọti-waini.

Ka pipe ipin Mik 6