Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mik 6:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ẹ gbọ́ nisisiyi ohun ti Oluwa wi; Dide, ba oke nla wijọ, si jẹ ki oke kékèké gbohùn rẹ.

2. Ẹ gbọ́ ẹjọ Oluwa, ẹnyin oke-nla, ati ẹnyin ipilẹ ilẹ̀ aiye: nitori Oluwa mba awọn enia rẹ̀ wijọ, yio si ba Israeli rojọ.

3. Enia mi, kini mo fi ṣe ọ? ati ninu kini mo fi da ọ li agara? dahùn si i.

4. Nitori mo ti mu ọ goke lati ilẹ Egipti wá, mo si rà ọ padà lati ile ẹrú wá; mo si rán Mose, Aaroni, ati Miriamu siwaju rẹ.

5. Enia mi, ranti nisisiyi ohun ti Balaki ọba Moabu gbèro, ati ohun ti Balaamu ọmọ Beori dá a lohùn lati Ṣittimu titi de Gilgali; ki ẹ ba le mọ̀ ododo Oluwa.

6. Kini emi o ha mu wá siwaju Oluwa, ti emi o fi tẹ̀ ara mi ba niwaju Ọlọrun giga? ki emi ha wá siwaju rẹ̀ pẹlu ọrẹ-ẹbọ sisun, pẹlu ọmọ malu ọlọdún kan?

7. Inu Oluwa yio ha dùn si ẹgbẹgbẹ̀run àgbo, tabi si ẹgbẹgbãrun iṣàn òroro? emi o ha fi àkọbi mi fun irekọja mi, iru-ọmọ inu mi fun ẹ̀ṣẹ ọkàn mi?

Ka pipe ipin Mik 6