Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mik 5:4-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. On o si duro yio si ma jẹ̀ li agbara Oluwa, ni ọlanla orukọ Oluwa Ọlọrun rẹ̀; nwọn o si wà, nitori nisisiyi ni on o tobi titi de opin aiye.

5. Eleyi ni yio jẹ alafia, nigbati ara Assiria yio wá si ilẹ wa; nigbati yio si tẹ̀ awọn ãfin wa mọlẹ, nigba nã li awa o gbe oluṣọ agutan meje dide si i, ati olori enia mẹjọ.

6. Nwọn o si fi idà pa ilẹ Assiria run, ati ilẹ Nimrodu ni àbawọ̀ inu rẹ̀: yio si gbà wa lọwọ ara Assiria nigbati o ba wá ilẹ wa, ati nigbati o ba si ntẹ̀ àgbegbe wa mọlẹ.

7. Iyokù Jakobu yio si wà lãrin ọ̀pọ enia bi irì lati ọdọ Oluwa wá, bi ọwarà òjo lori koriko, ti kì idara duro de enia, ti kì isi duro de awọn ọmọ enia.

8. Iyokù Jakobu yio si wà lãrin awọn Keferi, lãrin ọ̀pọ enia bi kiniun, lãrin awọn ẹranko igbo, bi ọmọkiniun lãrin agbo agutan; eyiti, bi o ba là a ja, ti itẹ̀ mọlẹ, ti isi ifa ya pẹrẹpẹrẹ, kò si ẹniti yio gbalà.

Ka pipe ipin Mik 5