Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mik 5:10-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Yio si ṣe li ọjọ na, ni Oluwa wi, ti emi o ke awọn ẹṣin rẹ kuro lãrin rẹ, emi o si pa awọn kẹkẹ́ ogun rẹ run.

11. Emi o si ke ilu-nla ilẹ rẹ kuro, emi o si tì gbogbo odi rẹ ṣubu:

12. Emi o si ke iwà-ajẹ kuro lọwọ rẹ: iwọ kì yio si ni alafọ̀ṣẹ mọ:

13. Ere fifin rẹ pẹlu li emi o ke kuro, awọn ere rẹ kuro lãrin rẹ; iwọ kì o si ma sin iṣẹ ọwọ́ rẹ mọ.

14. Emi o si tú igbo òriṣa rẹ kuro lãrin rẹ: emi o si pa awọn ilu rẹ run.

15. Emi o si gbẹsan ni ibinu ati irunu lara awọn keferi, ti nwọn kò ti igbọ́ ri.

Ka pipe ipin Mik 5