Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mik 5:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NISISIYI gbá ara rẹ jọ li ọwọ́, Iwọ ọmọbinrin ọwọ́: o ti dó tì wa; nwọn o fi ọ̀pa lu onidajọ Israeli li ẹ̀rẹkẹ.

2. Ati iwọ Betlehemu Efrata; bi iwọ ti jẹ kekere lãrin awọn ẹgbẹgbẹ̀run Juda, ninu rẹ ni ẹniti yio jẹ olori ni Israeli yio ti jade tọ̀ mi wá; ijade lọ rẹ̀ si jẹ lati igbãni, lati aiyeraiye.

3. Nitorina ni yio ṣe jọwọ wọn lọwọ, titi di akokò ti ẹniti nrọbi yio fi bi: iyokù awọn arakunrin rẹ̀ yio si pada wá sọdọ awọn ọmọ Israeli.

4. On o si duro yio si ma jẹ̀ li agbara Oluwa, ni ọlanla orukọ Oluwa Ọlọrun rẹ̀; nwọn o si wà, nitori nisisiyi ni on o tobi titi de opin aiye.

5. Eleyi ni yio jẹ alafia, nigbati ara Assiria yio wá si ilẹ wa; nigbati yio si tẹ̀ awọn ãfin wa mọlẹ, nigba nã li awa o gbe oluṣọ agutan meje dide si i, ati olori enia mẹjọ.

Ka pipe ipin Mik 5