Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mal 3:14-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Ẹnyin ti wipe, Asan ni lati sìn Ọlọrun: anfani kili o si wà, ti awa ti pa ilàna rẹ̀ mọ, ti awa si ti rìn ni igbãwẹ̀ niwaju Oluwa awọn ọmọ-ogun?

15. Ṣugbọn nisisiyi awa pè agberaga li alabùkunfun; lõtọ awọn ti o nhùwa buburu npọ si i; lõtọ, awọn ti o dán Oluwa wò li a dá si.

16. Nigbana li awọn ti o bẹ̀ru Oluwa mba ara wọn sọ̀rọ nigbakugba; Oluwa si tẹti si i, o si gbọ́, a si kọ iwe-iranti kan niwaju rẹ̀, fun awọn ti o bẹ̀ru Oluwa, ti nwọn si nṣe aṣaro orukọ rẹ̀.

17. Nwọn o si jẹ temi ni ini kan, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, li ọjọ na ti emi o dá; emi o si dá wọn si gẹgẹ bi enia iti ma dá ọmọ rẹ̀ si ti o nsìn i.

18. Nigbana li ẹnyin o yipada, ẹ o si mọ̀ iyatọ̀ lãrin olododo ati ẹni-buburu, lãrin ẹniti nsìn Ọlọrun, ati ẹniti kò sìn i.

Ka pipe ipin Mal 3