Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mal 2:1-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NJẸ nisisiyi, ẹnyin alufa, ofin yi ni fun nyin.

2. Bi ẹnyin kì o ba gbọ́, ti ẹnyin kì o ba fi si aiya, lati fi ogo fun orukọ mi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; emi o si rán egún si ori nyin, emi o si fi ibukun nyin ré, lõtọ mo ti fi ré na, nitori pe, ẹnyin kò fi i si ọkàn.

3. Wò o, emi o ba irugbìn nyin jẹ, emi o si fi igbẹ́ rẹ́ nyin loju, ani igbẹ́ asè ọ̀wọ nyin wọnni; a o si kó nyin lọ pẹlu rẹ̀.

4. Ẹnyin o si mọ̀ pe, emi li o ti rán ofin yi si nyin, ki majẹ̀mu mi le wà pẹlu Lefi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

5. Majẹmu mi ti iyè on alafia wà pẹlu rẹ̀; mo si fi wọn fun u, nitori bibẹ̀ru ti o bẹ̀ru mi, ti ẹ̀ru orukọ mi si bà a.

6. Ofin otitọ wà li ẹnu rẹ̀, a kò si ri ìwa-buburu li etè rẹ̀: o ba mi rìn li alafia ati ni ododo, o si yi ọ̀pọlọpọ kuro ninu ìwa-buburu.

7. Nitori ète alufa iba ma pa ìmọ mọ, ki nwọn ki o si ma wá ofin li ẹnu rẹ̀: nitori onṣẹ Oluwa awọn ọmọ-ogun li on iṣe.

8. Ṣugbọn ẹnyin ti yapa kuro li ọ̀na na: ẹnyin ti mu ọ̀pọlọpọ kọsẹ ninu ofin; ẹnyin ti ba majẹmu Lefi jẹ, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

9. Nitorina li emi pẹlu ṣe sọ nyin di ẹ̀gan, ati ẹni aikàsi niwaju gbogbo enia, niwọ̀n bi ẹnyin kò ti pa ọ̀na mi mọ, ti ẹnyin si ti nṣe ojusaju ninu ofin.

10. Baba kanna ki gbogbo wa ha ni? Ọlọrun kanna kó ha da wa bi? nitori kili awa ha ṣe nhùwa arekerekè olukuluku si arakunrin rẹ̀, nipa sisọ majẹmu awọn baba wa di alaimọ́.

11. Juda ti nhùwa arekerekè, a si ti nhùwa irira ni Israeli ati ni Jerusalemu: nitori Juda ti sọ ìwa mimọ́ Oluwa di alaimọ́, eyi ti o fẹ, o si ti gbe ọmọbinrin ọlọrun ajeji ni iyàwo.

12. Oluwa yio ke ọkunrin na ti o ṣe eyi kuro, olukọ ati ẹniti a nkọ, kuro ninu agọ Jakobu wọnni, ati ẹniti nrubọ ọrẹ si Oluwa awọn ọmọ-ogun.

13. Eyi li ẹnyin si tún ṣe, ẹnyin fi omije, ati ẹkún, ati igbe, bò pẹpẹ Oluwa mọlẹ, tobẹ̃ ti on kò fi kà ọrẹ nyin si mọ, tabi ki o fi inu-didùn gbà nkan lọwọ nyin.

14. Ṣugbọn ẹnyin wipe, Nitori kini? Nitori Oluwa ti ṣe ẹlẹri lãrin iwọ ati lãrin aya ewe rẹ, ẹniti iwọ ti nhùwa ẹ̀tan si: bẹ̃li ẹgbẹ́ rẹ li on sa iṣe, ati aya majẹmu rẹ.

15. On kò ha ti ṣe ọkan? bẹ̃li on ni iyokù ẹmi. Ẽ si ti ṣe jẹ ọkan? ki on ba le wá iru-ọmọ bi ti Ọlọrun. Nitorina ẹ tọju ẹmi nyin, ẹ má si jẹ ki ẹnikẹni hùwa ẹ̀tan si aya ewe rẹ̀.

Ka pipe ipin Mal 2