Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 4:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA si sọ fun Mose pe,

2. Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Bi ọkàn kan ba fi aimọ̀ sẹ̀ si ọkan ninu ofin OLUWA, li ohun ti kò yẹ ni ṣiṣe, ti o si ṣẹ̀ si ọkan ninu wọn:

3. Bi alufa ti a fi oróro yàn ba ṣẹ̀ gẹgẹ bi ẹ̀ṣẹ awọn enia; nigbana ni ki o mú ẹgbọrọ akọmalu kan alailabùku fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ wá fun OLUWA nitori ẹ̀ṣẹ ti o ti ṣẹ̀.

4. Ki o si mú akọmalu na wá si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ niwaju OLUWA; ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori akọmalu na, ki o si pa akọmalu na niwaju OLUWA.

5. Ki alufa na ti a fi oróro yàn, ki o bù ninu ẹ̀jẹ akọmalu na, ki o si mú u wá si agọ́ ajọ:

Ka pipe ipin Lef 4