Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 26:20-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Ẹnyin o si lò agbara nyin lasan: nitoriti ilẹ nyin ki yio mú ibisi rẹ̀ wá, bẹ̃ni igi ilẹ nyin ki yio so eso wọn.

21. Bi ẹnyin ba si nrìn lodi si mi, ti ẹnyin kò si gbọ́ ti emi; emi o si mú iyọnu ìgba meje wá si i lori nyin gẹgẹ bi ẹ̀ṣẹ nyin.

22. Emi o si rán ẹranko wá sinu nyin pẹlu, ti yio ma gbà nyin li ọmọ, ti yio si ma run nyin li ẹran-ọ̀sin, ti yio si mu nyin dinkù; opópo nyin yio si dahoro.

23. Bi ẹnyin kò ba gbà ìkilọ mi nipa nkan wọnyi, ṣugbọn ti ẹnyin o ma rìn lodi si mi;

24. Nigbana li emi pẹlu yio ma rìn lodi si nyin, emi o si jẹ nyin ni ìya si i ni ìgba meje nitori ẹ̀ṣẹ nyin.

25. Emi o si mú idà wá sori nyin, ti yio gbà ẹsan majẹmu mi; a o si kó nyin jọ pọ̀ ninu ilu nyin, emi o rán ajakalẹ-àrun sãrin nyin; a o si fi nyin lé ọtá lọwọ.

26. Nigbati mo ba ṣẹ́ ọpá onjẹ nyin, obinrin mẹwa yio yan àkara nyin ninu àro kan, ìwọ̀n ni nwọn o si ma fi fun nyin li àkara nyin: ẹnyin o si ma jẹ, ẹ ki yio si yó.

27. Ninu gbogbo eyi bi ẹnyin kò ba si gbọ́ ti emi, ti ẹ ba si nrìn lodi si mi;

28. Nigbana li emi o ma rìn lodi si nyin pẹlu ni ikannu; emi pẹlu yio si nà nyin ni ìgba meje nitori ẹ̀ṣẹ nyin.

29. Ẹnyin o si jẹ ẹran-ara awọn ọmọ nyin ọkunrin, ati ẹran-ara awọn ọmọ nyin obinrin li ẹnyin o jẹ.

30. Emi o si run ibi giga nyin wọnni, emi o si ke ere nyin lulẹ, emi o si wọ́ okú nyin sori okú oriṣa nyin; ọkàn mi yio si korira nyin.

31. Emi o si sọ ilu nyin di ahoro, emi o si sọ ibi mimọ́ nyin di ahoro, emi ki yio gbọ́ adùn õrùn didùn nyin mọ́.

Ka pipe ipin Lef 26