32. Ṣugbọn niti ilu awọn ọmọ Lefi, ile ilu iní wọn, ni awọn ọmọ Lefi o ma ràpada nigbakugba.
33. Bi ẹnikan ba si rà lọwọ awọn ọmọ Lefi, njẹ ile ti a tà na, ni ilu iní rẹ̀, ki o bọ́ ni jubeli: nitoripe ile ilu awọn ọmọ Lefi ni ilẹ-iní wọn lãrin awọn ọmọ Israeli.
34. Ṣugbọn ilẹ ẹba ilu wọn ni nwọn kò gbọdọ tà; nitoripe ilẹ-iní wọn ni titi aiye.
35. Ati bi arakunrin rẹ ba di talakà, ti ọwọ́ rẹ̀ ba si rẹlẹ lọdọ rẹ; njẹ ki iwọ ki o ràn a lọwọ; ibaṣe alejò, tabi atipo; ki on ki o le wà pẹlu rẹ.
36. Iwọ máṣe gbà elé lọwọ rẹ̀, tabi ẹdá; ṣugbọn bẹ̀ru Ọlọrun rẹ; ki arakunrin rẹ ki o le wà pẹlu rẹ.
37. Iwọ kò gbọdọ fi owo rẹ fun u li ẹdá, tabi ki o wín i li onjẹ rẹ fun asanlé.
38. Emi li OLUWA Ọlọrun nyin, ti o mú nyin lati ilẹ Egipti jade wá, lati fi ilẹ Kenaani fun nyin, ati lati ma ṣe Ọlọrun nyin.
39. Ati bi arakunrin rẹ ti mba ọ gbé ba di talakà, ti o si tà ara rẹ̀ fun ọ; iwọ kò gbọdọ sìn i ni ìsin-ẹrú: