2. Fi aṣẹ fun awọn ọmọ Israeli pe, ki nwọn ki o mú oróro daradara ti olifi gigún fun ọ wá, fun imọlẹ lati ma mu fitila jó nigbagbogbo.
3. Lẹhin ode aṣọ-ikele ẹrí, ninu agọ́ ajọ, ni ki Aaroni ki o tọju rẹ̀ lati aṣalẹ di owurọ̀ nigbagbogbo niwaju OLUWA: ìlana ni titilai ni iran-iran nyin.
4. Ki o si tọju fitila lori ọpá-fitila mimọ́ nì nigbagbogbo niwaju OLUWA.
5. Ki iwọ ki o si mú iyẹfun daradara, ki o si yan ìṣu-àkara mejila ninu rẹ̀: idamẹwa meji òṣuwọn ni ki o wà ninu ìṣu-àkara kan.
6. Ki iwọ ki o si tò wọn li ẹsẹ meji, mẹfa li ẹsẹ kan, lori tabili mimọ́ niwaju OLUWA.
7. Ki iwọ ki o si fi turari daradara sori ẹsẹ̀ kọkan ki o le wà lori ìṣu-àkara na fun iranti, ani ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA.