Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 19:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA si sọ fun Mose pe,

2. Sọ fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Ki ẹnyin ki o jẹ́ mimọ́: nitoripe Emi OLUWA Ọlọrun nyin jẹ́ mimọ́.

3. Ki olukuluku nyin ki o bẹ̀ru iya rẹ̀, ati baba rẹ̀, ki o si ma pa ọjọ́ isimi mi mọ́: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.

4. Ẹ máṣe yipada si ere, bẹ̃ni ki ẹnyin má si ṣe ṣe oriṣa didà fun ara nyin: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.

5. Bi ẹnyin ba si ru ẹbọ alafia si OLUWA, ki ẹnyin ki o ru u ki ẹ le di ẹni itẹwọgbà.

6. Li ọjọ́ ti ẹnyin ru ẹbọ na ni ki a jẹ ẹ, ati ni ijọ́ keji: bi ohun kan ba si kù ninu rẹ̀ titi di ijọ́ kẹta, ninu iná ni ki a sun u.

7. Bi a ba si jẹ ninu rẹ̀ rára ni ijọ́ kẹta, irira ni; ki yio dà:

8. Nitorina ẹniti o ba jẹ ẹ ni yio rù ẹ̀ṣẹ rẹ̀, nitoriti o bà ohun mimọ́ OLUWA jẹ́: ọkàn na li a o si ke kuro ninu awọn enia rẹ̀.

9. Ati nigbati ẹnyin ba nṣe ikore ilẹ nyin, iwọ kò gbọdọ ṣa igun oko rẹ li aṣatán, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ pa èṣẹ́ ikore rẹ.

10. Iwọ kò si gbọdọ pèṣẹ́ ọgbà-àjara rẹ, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ká gbogbo àjara ọgbà-àjara rẹ; ki iwọ ki o fi wọn silẹ fun awọn talaka ati alejò: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.

Ka pipe ipin Lef 19