Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 10:16-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Mose si fi pẹlẹpẹlẹ wá ewurẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ nì, si kiyesi i, a ti sun u: o si binu si Eleasari ati Itamari, awọn ọmọ Aaroni ti o kù, wipe,

17. Nitori kini ẹnyin kò ṣe jẹ ẹbọ èṣẹ na ni ibi mimọ́, nitoripe mimọ́ julọ ni, a si ti fi fun nyin lati rù ẹ̀ṣẹ ijọ enia, lati ṣètutu fun wọn niwaju OLUWA?

18. Kiyesi i, a kò mú ẹ̀jẹ rẹ̀ wá sinu ibi mimọ́: ẹnyin iba ti jẹ ẹ nitõtọ ni ibi mimọ́, bi mo ti paṣẹ.

19. Aaroni si wi fun Mose pe, Kiyesi i, li oni ni nwọn ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ wọn ati ẹbọ sisun wọn niwaju OLUWA; irú nkan wọnyi li o si ṣubulù mi: emi iba si ti jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ li oni, o ha le dara li oju OLUWA?

20. Nigbati Mose gbọ́ eyi inu rẹ̀ si tutù.

Ka pipe ipin Lef 10