orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jon 3 Yorùbá Bibeli (YCE)

Jona Gbọ́ràn sí OLUWA Lẹ́nu

1. Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ Jona wá lẹ̃keji, wipe,

2. Dide, lọ si Ninefe, ilu nla nì, ki o si kede si i, ikede ti mo sọ fun ọ.

3. Jona si dide, o si lọ si Ninefe, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa. Ninefe si jẹ ilu nla gidigidi tó irin ijọ mẹta.

4. Jona si bẹrẹsi wọ inu ilu na lọ ni irin ijọ kan, o si kede, o si wipe, Niwọn ogoji ọjọ si i, a o bì Ninefe wo.

5. Awọn enia Ninefe si gba Ọlọrun gbọ́, nwọn si kede awẹ̀, nwọn si wọ aṣọ ọ̀fọ, lati agbà wọn titi de kekere wọn.

6. Ọ̀rọ na si de ọdọ ọba Ninefe, o si dide kuro lori itẹ rẹ̀, o si bọ aṣọ igunwa rẹ̀ kuro lara rẹ̀, o si daṣọ ọ̀fọ bora, o si joko ninu ẽru.

7. O si kede rẹ̀, o si wi pe ki a là Ninefe ja nipa aṣẹ ọba, ati awọn agbagbà rẹ̀ pe, Máṣe jẹ ki enia, tabi ẹranko, ọwọ-ẹran tabi agbo-ẹran, tọ́ ohunkohun wò: má jẹ ki wọn jẹun, má jẹ ki wọn mu omi.

8. Ṣugbọn jẹ ki enia ati ẹranko fi aṣọ ọ̀fọ bora, ki nwọn si kigbe kikan si Ọlọrun: si jẹ ki nwọn yipada, olukuluku kuro li ọ̀na ibi rẹ̀, ati kuro ni ìwa agbara ti o wà lọwọ wọn.

9. Tani le mọ̀ bi Ọlọrun yio yipada ki o si ronupiwada, ki o si yipada kuro ni ibinu gbigbona rẹ̀, ki awa má ṣegbe?

10. Ọlọrun si ri iṣe wọn pe nwọn yipada kuro li ọ̀na ibi wọn: Ọlọrun si ronupiwada ibi ti on ti wi pe on o ṣe si wọn; on kò si ṣe e mọ.