Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joel 1:7-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. O ti pa àjara mi run, o si ti ya ẹ̀ka igi ọ̀pọtọ́ mi kuro, o ti bó o jalẹ, o si sọ ọ nù; awọn ẹ̀ka rẹ̀ li a si sọ di funfun.

8. Ẹ pohùnrére-ẹkun bi wundia ti a fi aṣọ ọ̀fọ dì li àmure, nitori ọkọ igbà ewe rẹ̀.

9. A ké ọrẹ-jijẹ ati ọrẹ-mimu kuro ni ile Oluwa; awọn alufa, awọn iranṣẹ Oluwa, ṣọ̀fọ.

10. Oko di ìgboro, ilẹ nṣọ̀fọ, nitori a fi ọkà ṣòfo: ọti-waini titun gbẹ, ororo mbuṣe.

11. Ki oju ki o tì nyin, ẹnyin agbẹ̀; ẹ hu, ẹnyin olùtọju àjara, nitori alikamà ati nitori ọkà barli; nitori ikorè oko ṣègbe.

12. Ajara gbẹ, igi ọ̀pọtọ́ si rọgbẹ; igi pomegranate, igi ọ̀pẹ pẹlu, ati igi appili, gbogbo igi igbo li o rọ: nitoriti ayọ̀ rọgbẹ kuro lọdọ awọn ọmọ enia.

13. Ẹ dì ara nyin li amùre, si pohùnrére ẹkún ẹnyin alufa: ẹ hu, ẹnyin iranṣẹ pẹpẹ: ẹ wá, fi gbogbo oru dùbulẹ ninu aṣọ-ọ̀fọ, ẹnyin iranṣẹ Ọlọrun mi: nitori ti a dá ọrẹ-jijẹ, ati ọrẹ-mimu duro ni ile Ọlọrun nyin.

14. Ẹ yà àwẹ kan si mimọ́, ẹ pè ajọ kan ti o ni irònu, ẹ pè awọn agbà, ati gbogbo awọn ará ilẹ na jọ si ile Oluwa Ọlọrun nyin, ki ẹ si kepe Oluwa,

15. A! fun ọjọ na, nitori ọjọ Oluwa kù si dẹ̀dẹ, ati bi iparun lati ọwọ́ Olodumare ni yio de.

16. A kò ha ké onjẹ kuro niwaju oju wa, ayọ̀ ati inu didùn kuro ninu ile Ọlọrun wa?

17. Irugbìn bajẹ ninu ebè wọn, a sọ aká di ahoro, a wó abà palẹ; nitoriti a mu ọ̀ka rọ.

18. Awọn ẹranko ti nkerora to! awọn agbo-ẹran dãmu, nitoriti nwọn kò ni papa oko; nitõtọ, a sọ awọn agbo agùtan di ahoro.

19. Oluwa, si ọ li emi o ké, nitori iná ti run pápa oko tutú aginju, ọwọ́ iná si ti jo gbogbo igi igbẹ.

Ka pipe ipin Joel 1