Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 9:24-35 Yorùbá Bibeli (YCE)

24. A fi aiye le ọwọ enia buburu; o si bò awọn onidajọ rẹ̀ li oju; bi kò ba ri bẹ̃, njẹ tani?

25. Njẹ nisisiyi ọjọ mi yara jù onṣẹ lọ, nwọn fò lọ, nwọn kò ri ire.

26. Nwọn kọja lọ bi ọkọ-ẽsú ti nsure lọ; bi idì ti o nyara si ohun ọdẹ.

27. Bi emi ba wipe, emi o gbagbe aro ibinujẹ mi, emi o fi ọkàn lelẹ̀, emi o si rẹ̀ ara mi lẹkun.

28. Ẹ̀ru ibinujẹ mi gbogbo bà mi, emi mọ̀ pe iwọ kì yio mu mi bi alaiṣẹ̀.

29. Bi o ba ṣepe enia buburu li emi, njẹ kili emi nṣe lãlã lasan si!

30. Bi mo tilẹ fi omi òjo didì wẹ̀ ara mi, ti mo fi omi-aró wẹ̀ ọwọ mi mọ́,

31. Sibẹ iwọ o gbe mi bọ̀ inu ihò ọ̀gọdọ, aṣọ ara mi yio sọ mi di ẹni-irira.

32. Nitori on kì iṣe enia bi emi, ti emi o fi da a lohùn ti awa o fi pade ni idajọ.

33. Bẹ̃ni kò si alatunṣe kan lagbedemeji wa, ti iba fi ọwọ rẹ̀ le awa mejeji lara.

34. Ki on sa mu ọ̀pa rẹ̀ kuro lara mi, ki ìbẹru rẹ̀ ki o má si ṣe daiya fò mi.

35. Nigbana ni emi iba sọ̀rọ, emi kì ba si bẹ̀ru rẹ̀; ṣugbọn kò ri bẹ̃ fun mi.

Ka pipe ipin Job 9