Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 9:16-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Bi emi ba si kepè e, ti on si da mi lohùn, emi kì yio si gbagbọ pe, on ti feti si ohùn mi.

17. Nitoripe o fi ẹ̀fufu nla ṣẹ mi tutu, o sọ ọgbẹ mi di pipọ lainidi.

18. On kì yio jẹ ki emi ki o fà ẹmi mi, ṣugbọn o fi ohun kikorò kún u fun mi.

19. Bi mo ba sọ ti agbara, wò o! alagbara ni, tabi niti idajọ, tani yio da akoko fun mi lati rò?

20. Bi mo tilẹ da ara mi lare, ẹnu ara mi ni yio dá mi lẹbi; bi mo wipe, olododo li emi, yio si fi mi hàn ni ẹni-òdi.

21. Olõtọ ni mo ṣe, sibẹ emi kò kiyesi ẹmi mi, ìwa mi li emi iba ma gàn.

22. Ohun kanna ni, nitorina ni emi ṣe sọ ọ: on a pa ẹni-otitọ ati enia buburu pẹlu.

23. Bi jamba ba pa ni lojijì, yio rẹrin idanwo alaiṣẹ̀.

24. A fi aiye le ọwọ enia buburu; o si bò awọn onidajọ rẹ̀ li oju; bi kò ba ri bẹ̃, njẹ tani?

25. Njẹ nisisiyi ọjọ mi yara jù onṣẹ lọ, nwọn fò lọ, nwọn kò ri ire.

26. Nwọn kọja lọ bi ọkọ-ẽsú ti nsure lọ; bi idì ti o nyara si ohun ọdẹ.

Ka pipe ipin Job 9