Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 8:6-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Iwọ iba mọ́, ki o si duro ṣinṣin: njẹ nitõtọ nisisiyi on o tají fun ọ, on a si sọ ibujoko ododo rẹ di pipọ.

7. Ipilẹṣẹ rẹ iba tilẹ kere ri, bẹ̃ni igbẹhin rẹ iba pọ̀ si i gidigidi.

8. Emi bẹ̀ ọ njẹ, bere lọwọ awọn ara igbãni, ki o si kiyesi iwádi awọn baba wọn.

9. Nitoripe ọmọ-àná li awa, a kò si mọ̀ nkan, nitoripe òjiji li ọjọ wa li aiye.

10. Awọn kì yio ha kọ́ ọ, nwọn kì yio si sọ fun ọ, nwọn kì yio si sọ̀rọ lati inu ọkàn wọn jade wá?

Ka pipe ipin Job 8