Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 8:12-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Nigbati o wà ni tutù, ti a kò ke e lulẹ̀, o rọ danu sin eweko miran gbogbo.

13. Bẹ̃ni ipa ọ̀na gbogbo awọn ti o gbagbe Ọlọrun, abá awọn àgabàgebe yio di ofo.

14. Abá ẹniti a o ke kuro, ati igbẹkẹle ẹniti o dàbi ile alantakùn.

15. Yio fi ara tì ile rẹ̀, ṣugbọn kì yio le iduro, yio fi di ara rẹ̀ mu ṣinṣin ṣugbọn kì yio le iduro pẹ.

16. O tutù niwaju õrùn, ẹka rẹ̀ si yọ jade ninu ọgbà rẹ̀.

17. Gbòngbo rẹ̀ ta yi ebè ka, o si wò ibi okuta wọnni.

18. Bi o ba si pa a run kuro ni ipò rẹ̀, nigbana ni ipò na yio sẹ ẹ pe: emi kò ri ọ ri!

19. Kiyesi eyi ni ayọ̀ ọ̀na rẹ̀ ati lati inu ilẹ li omiran yio ti hù jade wá.

20. Kiyesi i, Ọlọrun kì yio ta ẹni-otitọ nù, bẹ̃ni kì yio ràn oniwa-buburu lọwọ.

21. Titi yio fi fi ẹ̀rin kún ọ li ẹnu, ati ète rẹ pẹlu iho ayọ̀.

22. Itiju li a o fi bò awọn ti o korira rẹ, ati ibujoko enia buburu kì yio si mọ.

Ka pipe ipin Job 8