Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 5:9-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Ẹniti o ṣe ohun ti o tobi, ti a kò lè iṣe awári, ohun iyanu laini iye.

10. Ti nrọ̀jo si ilẹ aiye, ti o si nrán omi sinu ilẹ̀kilẹ.

11. Lati gbe awọn onirẹlẹ leke, ki a le igbé awọn ẹni ibinujẹ ga si ibi ailewu.

12. O yi ìmọ awọn alarekerekè po, bẹ̃li ọwọ wọn kò lè imu idawọle wọn ṣẹ.

13. O mu awọn ọlọgbọ́n ninu arekereke ara wọn, ati ìmọ awọn onroro li o tãri ṣubu li ògedengbè.

14. Nwọn sure wọ inu òkunkun li ọ̀san, nwọn si nfọwọ talẹ̀ li ọ̀sangangan bi ẹnipe li oru.

15. Ṣugbọn o gba talakà là kuro li ọwọ idà, lọwọ ẹnu wọn, ati lọwọ awọn alagbara.

16. Bẹ̃ni abá wà fun talaka, aiṣotitọ si pa ẹnu rẹ̀ mọ.

17. Kiyesi i, ibukún ni fun ẹniti Ọlọrun bawi, nitorina má ṣe gan ìbawi Olodumare.

18. Nitoripe on a mu ni lara kan, a si di idi itura, o ṣa lọgbẹ, ọwọ rẹ̀ a si mu jina.

19. Yio gbà ọ ninu ipọnju mẹfa, ani ninu meje ibi kan kì yio ba ọ.

Ka pipe ipin Job 5