Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 5:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NJẸ pè nisisiyi! bi ẹnikan ba wà ti yio da ọ lohùn, tabi tani ninu awọn ẹni-mimọ́ ti iwọ o wò?

2. Nitoripe ibinu pa alaimoye, irúnu a si pa òpe enia.

3. Emi ti ri alaimoye ti o ta gbongbò mulẹ̀, ṣugbọn lojukanna mo fi ibujoko rẹ̀ bú.

4. Awọn ọmọ rẹ̀ kò jina sinu ewu, a si tẹ̀ wọn mọlẹ loju ibode, bẹ̃ni kò si alãbò kan.

5. Ikore oko ẹniti awọn ẹniti ebi npa jẹrun, ti nwọn si wọnú ẹ̀gun lọ ikó, awọn igara si gbe ohùn ini wọn mì.

6. Bi ipọnju kò tilẹ̀ tinu erupẹ jade wá nì, ti iyọnu kò si tinu ilẹ hù jade wá.

7. Ṣugbọn a bi enia sinu wàhala, gẹgẹ bi ìpẹpẹ iná ti ima ta sokè.

8. Sọdọ Ọlọrun li emi lè ma ṣe awári, li ọwọ Ọlọrun li emi lè ma fi ọ̀ran mi le.

9. Ẹniti o ṣe ohun ti o tobi, ti a kò lè iṣe awári, ohun iyanu laini iye.

10. Ti nrọ̀jo si ilẹ aiye, ti o si nrán omi sinu ilẹ̀kilẹ.

11. Lati gbe awọn onirẹlẹ leke, ki a le igbé awọn ẹni ibinujẹ ga si ibi ailewu.

12. O yi ìmọ awọn alarekerekè po, bẹ̃li ọwọ wọn kò lè imu idawọle wọn ṣẹ.

Ka pipe ipin Job 5