Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 42:3-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Tani ẹniti nfi ìgbimọ pamọ laini ìmọ? nitorina ni emi ṣe nsọ eyi ti emi kò mọ̀, ohun ti o ṣe iyanu jọjọ niwaju mi, ti emi kò moye.

4. Emi bẹ̀ ọ, gbọ́, emi o si sọ, emi o bère lọwọ rẹ, ki iwọ ki o si bùn mi ni oye.

5. Emi ti fi gbigbọ́ eti gburo rẹ, ṣugbọn nisisiyi oju mi ti ri ọ.

6. Njẹ nitorina emi korira ara mi, mo si ronupiwada ṣe tóto ninu ekuru ati ẽru.

7. Bẹ̃li o si ri, lẹhin igbati OLUWA ti sọ ọ̀rọ wọnyi tan fun Jobu, OLUWA si wi fun Elifasi, ara Tema pe, Mo binu si ọ ati si awọn ọrẹ́ rẹ mejeji, nitoripe ẹnyin kò sọ̀rọ niti emi, ohun ti o tọ́ bi Jobu iranṣẹ mi ti sọ.

8. Nitorina ẹ mu akọ ẹgbọrọ malu meje, ati àgbo meje, ki ẹ si tọ̀ Jobu iranṣẹ mi lọ, ki ẹ si fi rú ẹbọ sisun fun ara nyin: Jobu iranṣẹ mi yio si gbadura fun nyin: nitoripe oju rẹ̀ ni mo gbà; ki emi ki o má ba ṣe si nyin bi iṣina nyin, niti ẹnyin kò sọ̀rọ ohun ti o tọ́ si mi bi Jobu iranṣẹ mi.

9. Bẹ̃ni Elifasi, ara Tema, ati Bildadi, ara Ṣua, ati Sofari, ara Naama lọ, nwọn si ṣe gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun wọn: OLUWA si gbà oju Jobu.

Ka pipe ipin Job 42