24. Aiya rẹ̀ duro gbagigbagi bi okuta, ani o le bi iya-ọlọ.
25. Nigbati o ba gbe ara rẹ̀ soke, awọn alagbara a bẹ̀ru, nitori ìbẹru nla, nwọn damu.
26. Idà ẹniti o ṣa a kò le iràn a, ọ̀kọ, ẹṣin tabi ọfa.
27. O ka irin si bi koriko gbigbẹ, ati idẹ si bi igi hihù.
28. Ọfa kò le imu u sá, okuta kànakana lọdọ rẹ̀ dabi akeku koriko.
29. O ka ẹṣin si bi akeku idi koriko, o rẹrin si ìmisi ọ̀kọ.
30. Okuta mimú mbẹ nisalẹ abẹ rẹ̀, o si tẹ́ ohun mimú ṣonṣo sori ẹrẹ.
31. O mu ibu omi hó bi ìkoko, o sọ agbami okun dabi kolobó ìkunra.
32. O mu ipa-ọ̀na tàn lẹhin rẹ̀, enia a ma ka ibu si ewú arugbo.
33. Lori ilẹ aiye kò si iru rẹ̀, ti a da laini ìbẹru.
34. O bojuwo ohun giga gbogbo, o si nikan jasi ọba lori gbogbo awọn ọmọ igberaga.