Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 41:22-34 Yorùbá Bibeli (YCE)

22. Li ọrùn rẹ̀ li agbara kù si, ati ibinujẹ aiya si pada di ayọ̀ niwaju rẹ̀.

23. Jabajaba ẹran rẹ̀ dijọ pọ̀, nwọn mura giri fun ara wọn, a kò le iṣi wọn ni ipò.

24. Aiya rẹ̀ duro gbagigbagi bi okuta, ani o le bi iya-ọlọ.

25. Nigbati o ba gbe ara rẹ̀ soke, awọn alagbara a bẹ̀ru, nitori ìbẹru nla, nwọn damu.

26. Idà ẹniti o ṣa a kò le iràn a, ọ̀kọ, ẹṣin tabi ọfa.

27. O ka irin si bi koriko gbigbẹ, ati idẹ si bi igi hihù.

28. Ọfa kò le imu u sá, okuta kànakana lọdọ rẹ̀ dabi akeku koriko.

29. O ka ẹṣin si bi akeku idi koriko, o rẹrin si ìmisi ọ̀kọ.

30. Okuta mimú mbẹ nisalẹ abẹ rẹ̀, o si tẹ́ ohun mimú ṣonṣo sori ẹrẹ.

31. O mu ibu omi hó bi ìkoko, o sọ agbami okun dabi kolobó ìkunra.

32. O mu ipa-ọ̀na tàn lẹhin rẹ̀, enia a ma ka ibu si ewú arugbo.

33. Lori ilẹ aiye kò si iru rẹ̀, ti a da laini ìbẹru.

34. O bojuwo ohun giga gbogbo, o si nikan jasi ọba lori gbogbo awọn ọmọ igberaga.

Ka pipe ipin Job 41