Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 40:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA da Jobu lohùn si i pẹlu, o si wipe,

2. Ẹniti mba Olodumare jà, yio ha kọ́ ọ li ẹkọ́? ẹniti mba Ọlọrun wi, jẹ ki o dahùn!

3. Nigbana ni Jobu da Oluwa lohùn, o si wipe:

4. Kiyesi i, ẹgbin li emi; ohùn kili emi o da? emi o fi ọwọ mi le ẹnu mi.

5. Ẹ̃kan ni mo sọ̀rọ̀, ṣugbọn emi kì yio si tun sọ mọ, lẹ̃meji ni, emi kò si le iṣe e mọ́.

6. Nigbana ni OLUWA da Jobu lohùn lati inu ìji ajayika wá o si wipe:

7. Di àmure giri li ẹgbẹ rẹ bi ọkunrin, emi o bi ọ lere, ki iwọ ki o si kọ́ mi li ẹkọ́.

8. Iwọ ha fẹ imu idajọ mi di asan? iwọ o si da mi lẹbi, ki iwọ ki o le iṣe olododo?

9. Iwọ ni apá bi Ọlọrun, tabi iwọ le ifi ohùn san ãrá bi on?

10. Fi ọlanla ati ọla-itayọ ṣe ara rẹ li ọṣọ, ki o si fi ogo ati ẹwa ọṣọ bò ara rẹ li aṣọ.

11. Mu irunu ibinu rẹ jade, kiyesi gbogbo ìwa igberaga, ki o si rẹ̀ ẹ silẹ.

Ka pipe ipin Job 40