Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 39:2-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Iwọ le ika iye oṣu ti nwọn npé, iwọ si mọ̀ àkoko igba ti nwọn ibi?

3. Nwọn tẹ ara wọn ba, nwọn bimọ wọn, nwọn si mu ikãnu wọn jade.

4. Awọn ọmọ wọn ri daradara, nwọn dagba ninu ọ̀dan, nwọn jade lọ, nwọn kò si tun pada wá mọ́ sọdọ wọn.

5. Tali o jọ̃ kẹtẹkẹtẹ-oko lọwọ, tabi tali o tú ide kẹtẹkẹtẹ igbẹ́?

6. Eyi ti mo fi aginju ṣe ile fun, ati ilẹ iyọ̀ ni ibugbe rẹ̀.

7. O rẹrin si ariwo ilu, bẹ̃ni on kò si gbọ́ igbe darandaran.

8. Ori àtòle oke-nla ni ibujẹ oko rẹ̀, on a si ma wá ewe tutu gbogbo ri.

9. Agbanrere ha jẹ sìn ọ bi, tabi o jẹ duro ni ibujẹ ẹran rẹ?

10. Iwọ le ifi kátà dè agbanrere ninu aporo, tabi o jẹ ma fà itulẹ ninu aporo oko tọ̀ ọ lẹhin?

11. Iwọ o gbẹkẹlẹ e, nitori agbara rẹ̀ pọ̀, iwọ o si fi iṣẹ rẹ le e li ọwọ?

12. Iwọ le igbẹkẹle e pe, yio mu eso oko rẹ wá sile; pe, yio si ko o jọ sinu àka rẹ̀?

13. Iyẹ abo-ogongo nfi ayọ̀ fì, iyẹ ati ihuhu rẹ̀ daradara ni bi?

14. Kò ri bẹ̃? o fi ẹyin rẹ̀ silẹ-yilẹ, a si mu wọn gbona ninu ekuru.

15. Ti o si gbagbe pe, ẹsẹ le itẹ wọn fọ, tabi pe, ẹranko igbẹ le itẹ wọn fọ:

16. Kò ni ãjo si awọn ọmọ rẹ̀ bi ẹnipe nwọn kì iṣe tirẹ̀, asan ni iṣẹ rẹ̀ laibẹru:

Ka pipe ipin Job 39