Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 39:10-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Iwọ le ifi kátà dè agbanrere ninu aporo, tabi o jẹ ma fà itulẹ ninu aporo oko tọ̀ ọ lẹhin?

11. Iwọ o gbẹkẹlẹ e, nitori agbara rẹ̀ pọ̀, iwọ o si fi iṣẹ rẹ le e li ọwọ?

12. Iwọ le igbẹkẹle e pe, yio mu eso oko rẹ wá sile; pe, yio si ko o jọ sinu àka rẹ̀?

13. Iyẹ abo-ogongo nfi ayọ̀ fì, iyẹ ati ihuhu rẹ̀ daradara ni bi?

14. Kò ri bẹ̃? o fi ẹyin rẹ̀ silẹ-yilẹ, a si mu wọn gbona ninu ekuru.

15. Ti o si gbagbe pe, ẹsẹ le itẹ wọn fọ, tabi pe, ẹranko igbẹ le itẹ wọn fọ:

16. Kò ni ãjo si awọn ọmọ rẹ̀ bi ẹnipe nwọn kì iṣe tirẹ̀, asan ni iṣẹ rẹ̀ laibẹru:

17. Nitoripe Ọlọrun dù u li ọgbọ́n, bẹ̃ni kò si fi ipin oye fun u.

18. Nigbati o gbe ara soke, o gàn ẹṣin ati ẹlẹṣin.

19. Iwọ li o fi agbara fun ẹṣin, iwọ li o fi gọ̀gọ wọ ọrùn rẹ̀ li aṣọ?

20. Iwọ le imu u fò soke bi ẹlẹnga, ogo ẽmi imu rẹ̀ ni ẹ̀ru-nla.

21. O fi ẹsẹ halẹ ninu aporo, o si yọ̀ si agbara rẹ̀; o nlọ jade lati pade awọn ahamọra ogun.

22. O fi oju kekere wò ẹ̀ru, aiya kò si fò o; bẹ̃ni kì isi ipada sẹhin kuro lọwọ idà.

23. Lọdọ rẹ̀ ni apo-ọfa nmi pẹkẹpẹkẹ, ati ọ̀kọ didan ati apata.

24. On fi kikoro oju ati ibinu nla gbe ilẹ mì, bẹ̃li on kò si gbagbọ pe, iro ipè ni.

25. O wi ni igba ipè pe, Ha! Ha! o si gborùn ogun lokere rere: ãrá awọn balogun ati ihó àyọ wọn.

26. Awodi a ma ti ipa ọgbọ́n rẹ fò soke, ti o si nà iyẹ apa rẹ̀ siha gusu?

Ka pipe ipin Job 39