Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 38:29-41 Yorùbá Bibeli (YCE)

29. Lati inu tani ìdi omi ti jade wá, ati ìri didi ọrun tali o bi i?

30. Omi bò o mọlẹ bi ẹnipe labẹ okuta, oju ibú nla si dìlupọ̀.

31. Iwọ le ifi ọja de awọn irawọ meje [Pleyade] tabi iwọ le itudi irawọ Orionu?

32. Iwọ le imu awọn ami mejejila irawọ [Massaroti] jade wá ni igba akoko wọn? tabi iwọ le iṣe àmọna Arketuru pẹlu awọn ọmọ rẹ̀?

33. Iwọ mọ̀ ilana-ilana ọrun, iwọ le ifi ijọba rẹ̀ lelẹ li aiye?

34. Iwọ le igbé ohùn rẹ soke de awọsanma, ki ọ̀pọlọpọ omi ki o le bò ọ?

35. Iwọ le iran mànamána ki nwọn ki o le ilọ, ki nwọn ki o si wi fun ọ pe, Awa nĩ!

36. Tali o fi ọgbọ́n si odo-inu, tabi tali o fi oye sinu aiya?

37. Tali o fi ọgbọ́n ka iye awọsanma, tali o si mu igo ọrun dàjade.

38. Nigbati erupẹ di lile, ati ogulutu dipọ̀?

39. Iwọ o ha dẹ ọdẹ fun abo kiniun bi, iwọ o si tẹ́ ebi ẹgbọrọ kiniun lọrun?

40. Nigbati nwọn ba mọlẹ ninu iho wọn, ti nwọn si ba ni ibuba de ohun ọdẹ.

41. Tani npese ohun jijẹ fun ìwo? nigbati awọn ọmọ rẹ̀ nkepe Ọlọrun, nwọn a ma fò kiri nitori aili ohun jijẹ.

Ka pipe ipin Job 38