Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 38:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBANA ni OLUWA da Jobu lohùn lati inu ìji ajayika wá o si wipe,

2. Tani eyi ti nfi ọ̀rọ aini igbiro ṣú ìmọ li òkunkun.

3. Di ẹgbẹ ara rẹ li amure bi ọkunrin nisisiyi, nitoripe emi o bère lọwọ rẹ ki o si da mi lohùn.

4. Nibo ni iwọ wà nigbati mo fi ipilẹ aiye sọlẹ? wi bi iwọ ba moye!

5. Tali o fi ìwọn rẹ̀ lelẹ, bi iwọ ba mọ̀, tabi tani o ta okun wiwọn sori rẹ̀.

6. Lori ibo ni a gbe kan ipilẹ rẹ̀ mọ́, tabi tali o fi okuta igun rẹ̀ le ilẹ?

7. Nigbati awọn irawọ owurọ jumọ kọrin pọ̀, ti gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun nhó iho ayọ̀?

8. Tabi tali o fi ilẹkun sé omi okun mọ́, nigbati o ya jade bi ẹnipe o ti inu tu jade wá?

9. Nigbati mo fi awọsanma ṣe aṣọ rẹ̀, ati òkunkun ṣiṣu ṣe ọ̀ja igbanu rẹ̀?

10. Ti mo ti paṣẹ ipinnu mi fun u, ti mo si ṣe bèbe ati ilẹkun.

11. Ti mo si wipe, Nihinyi ni iwọ o dé, ki o má si rekọja, nihinyi si ni igberaga riru omi rẹ yio gbe duro mọ.

12. Iwọ paṣẹ fun owurọ lati igba ọjọ rẹ̀ wá, iwọ si mu ila-õrun mọ̀ ipo rẹ̀?

Ka pipe ipin Job 38