Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 34:23-33 Yorùbá Bibeli (YCE)

23. Nitoripe on kò pẹ ati kiyesi ẹnikan, ki on ki o si mu u lọ sinu idajọ niwaju Ọlọrun.

24. On o fọ awọn alagbara tútu laini-iwadi, a si fi ẹlomiran dipo wọn,

25. Nitoripe o mọ̀ iṣẹ wọn, o si yi wọn po di oru, bẹ̃ni nwọn di itẹrẹ́ pọ̀.

26. O kọlu wọn bi enia buburu, nibiti awọn ẹlomiran ri i.

27. Nitorina ni nwọn pada kẹhinda si i, nwọn kò si ti fiyesi ipa-ọ̀na rẹ̀ gbogbo.

28. Ki nwọn ki o si mu igbe ẹkún awọn talaka lọ de ọdọ rẹ̀, on si gbọ́ igbe ẹkún olupọnju.

29. Nigbati o ba fun ni ni irọra, tani yio da a lẹbi, nigbati o ba pa oju rẹ̀ mọ, tani yio le iri i? bẹ̃ni o ṣe e si orilẹ-ède tabi si enia kanṣoṣo.

30. Ki agabagebe ki o má ba jọba, ki nwọn ki o má di idẹwo fun enia.

31. Nitoripe ẹnikan ha le wi fun Ọlọrun pe, emi jiya laiṣẹ̀?

32. Eyi ti emi kò ri, iwọ fi kọ́ mi, bi mo ba si dẹṣẹ, emi kì yio ṣe bẹ̃ mọ́.

33. Iṣe bi ti inu rẹ pe, on o san ẹ̀san pada? njẹ on yio san a pada, iwọ iba kọ̀ ọ tabi iwọ iba fẹ ẹ, kì iṣe emi, pẹlupẹlu kili iwọ mọ̀, sọ ọ!

Ka pipe ipin Job 34