Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 34:19-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Ambọtori fun ẹniti kì iṣojuṣaju awọn ọmọ-alade, tabi ti kò kà ọlọrọ̀ si jù talaka lọ, nitoripe iṣẹ ọwọ rẹ̀ ni gbogbo wọn iṣe.

20. Ni iṣẹju kan ni nwọn o kú, awọn enia a si di yiyọ lẹnu larin ọganjọ, nwọn a si kọja lọ; a si mu awọn alagbara kuro laifi ọwọ́ ṣe.

21. Nitoripe oju rẹ̀ mbẹ ni ipa-ọ̀na enia, on si ri irin rẹ̀ gbogbo.

22. Kò si òkunkun, tabi ojiji ikú, nibiti awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ yio gbe sapamọ si.

23. Nitoripe on kò pẹ ati kiyesi ẹnikan, ki on ki o si mu u lọ sinu idajọ niwaju Ọlọrun.

24. On o fọ awọn alagbara tútu laini-iwadi, a si fi ẹlomiran dipo wọn,

25. Nitoripe o mọ̀ iṣẹ wọn, o si yi wọn po di oru, bẹ̃ni nwọn di itẹrẹ́ pọ̀.

26. O kọlu wọn bi enia buburu, nibiti awọn ẹlomiran ri i.

27. Nitorina ni nwọn pada kẹhinda si i, nwọn kò si ti fiyesi ipa-ọ̀na rẹ̀ gbogbo.

28. Ki nwọn ki o si mu igbe ẹkún awọn talaka lọ de ọdọ rẹ̀, on si gbọ́ igbe ẹkún olupọnju.

Ka pipe ipin Job 34