Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 34:12-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Nitõtọ Ọlọrun kì yio hùwakiwa, bẹ̃ni Olodumare kì yio yi idajọ po.

13. Tani o fi itọju aiye lé e lọwọ, tabi tali o to gbogbo aiye lẹsẹlẹsẹ?

14. Bi o ba gbe aiya rẹ̀ le kiki ara rẹ̀, ti o si gba ọkàn rẹ̀ ati ẹmi rẹ̀ sọdọ ara rẹ̀,

15. Gbogbo enia ni yio parun pọ̀, enia a si tun pada di erupẹ.

16. Njẹ nisisiyi, bi iwọ ba ni oye, gbọ́ eyi, fetisi ohùn ẹnu mi.

17. Ẹniti o korira otitọ le iṣe olori bi? iwọ o ha si da olõtọ-ntọ̀ lẹbi?

18. O ha tọ́ lati wi fun ọba pe, Enia buburu ni iwọ, tabi fun awọn ọmọ-alade pe, Alaimọ-lọrun li ẹnyin?

19. Ambọtori fun ẹniti kì iṣojuṣaju awọn ọmọ-alade, tabi ti kò kà ọlọrọ̀ si jù talaka lọ, nitoripe iṣẹ ọwọ rẹ̀ ni gbogbo wọn iṣe.

20. Ni iṣẹju kan ni nwọn o kú, awọn enia a si di yiyọ lẹnu larin ọganjọ, nwọn a si kọja lọ; a si mu awọn alagbara kuro laifi ọwọ́ ṣe.

21. Nitoripe oju rẹ̀ mbẹ ni ipa-ọ̀na enia, on si ri irin rẹ̀ gbogbo.

22. Kò si òkunkun, tabi ojiji ikú, nibiti awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ yio gbe sapamọ si.

Ka pipe ipin Job 34