Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 34:1-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. PẸLUPẸLU Elihu dahùn o si wipe,

2. Ẹnyin ọlọgbọ́n, ẹ gbọ́ ọ̀rọ mi, ki ẹ si dẹtisilẹ si mi, ẹnyin ti ẹ ni ìmoye.

3. Nitoripe eti a ma dán ọ̀rọ wò, bi adùn ẹnu ti itọ onjẹ wò.

4. Ẹ jẹ ki a ṣà idajọ yàn fun ara wa; ẹ jẹ ki a mọ̀ ohun ti o dara larin wa.

5. Nitoripe Jobu wipe, Olododo li emi; Ọlọrun si ti gbà idajọ mi lọ.

6. Emi ha lè ipurọ si itọsí mi bi, ọfa mi kò ni awọtan, laiṣẹ ni.

7. Ọkunrin wo li o dabi Jobu, ti nmu ẹ̀gan bi ẹni mu omi.

8. Ti mba awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ kẹgbẹ, ti o si mba awọn enia buburu rin.

9. Nitori o sa ti wipe, Ère kan kò si fun enia, ti yio fi ma ṣe inu didun si Ọlọrun,

10. Njẹ nitorina, ẹ fetisilẹ si mi, ẹnyin enia amoye: odõdi fun Ọlọrun ti iba fi huwa buburu, ati fun Olodumare, ti yio fi ṣe aiṣedede!

11. Nitoripe ẹsan iṣẹ enia ni yio san fun u, yio si mu olukuluku ki o ri gẹgẹ bi ipa-ọ̀na rẹ̀.

12. Nitõtọ Ọlọrun kì yio hùwakiwa, bẹ̃ni Olodumare kì yio yi idajọ po.

13. Tani o fi itọju aiye lé e lọwọ, tabi tali o to gbogbo aiye lẹsẹlẹsẹ?

14. Bi o ba gbe aiya rẹ̀ le kiki ara rẹ̀, ti o si gba ọkàn rẹ̀ ati ẹmi rẹ̀ sọdọ ara rẹ̀,

15. Gbogbo enia ni yio parun pọ̀, enia a si tun pada di erupẹ.

16. Njẹ nisisiyi, bi iwọ ba ni oye, gbọ́ eyi, fetisi ohùn ẹnu mi.

Ka pipe ipin Job 34