Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 32:5-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Nigbati Elihu ri pe idahùn ọ̀rọ kò si li ẹnu awọn ọkunrin mẹtẹta wọnyi, nigbana ni o binu.

6. Elihu, ọmọ Barakeli, ara Busi, dahùn o si wipe, Ọmọde li emi, àgba si li ẹnyin; njẹ nitorina ni mo duro, mo si mbẹ̀ru lati fi ìmọ mi hàn nyin.

7. Emi wipe, ọjọ-jọjọ ni iba sọ̀rọ, ati ọ̀pọlọpọ ọdun ni iba ma kọ́ni li ọgbọ́n.

8. Ṣugbọn ẹmi kan ni o wà ninu enia, ati imisi Olodumare ni isi ma fun wọn li oye.

9. Enia nlanla kì iṣe ọlọgbọ́n, bẹ̃ni awọn àgba li oye idajọ kò ye.

10. Nitorina li emi ṣe wipe, ẹ dẹtisilẹ si mi, emi pẹlu yio fi ìmọ mi hàn.

11. Kiyesi i, emi ti duro de ọ̀rọ nyin, emi fetisi aroye nyin, nigbati ẹnyin nwá ọ̀rọ ti ẹnyin o sọ.

12. Ani mo fiyesi nyin tinutinu, si kiyesi i, kò si ẹnikan ninu nyin ti o le já Jobu li irọ́, tabi ti o lè ida a lohùn ọ̀rọ rẹ̀!

13. Ki ẹnyin ki o má ba wipe, awa wá ọgbọ́n li awari: Ọlọrun li o lè bi i ṣubu, kì iṣe enia.

14. Bi on kò ti sọ̀rọ si mi, bẹ̃li emi kì yio fi ọ̀rọ nyin da a lohùn.

15. Ẹnu si yà wọn, nwọn kò si dahùn mọ́, nwọn ṣiwọ ọ̀rọ isọ.

16. Mo si reti, nitoriti nwọn kò si fọhùn, nwọn dakẹ jẹ, nwọn kò si dahùn mọ́.

17. Bẹ̃li emi o si dahùn nipa ti emi, emi pẹlu yio si fi ìmọ mi hàn.

18. Nitoripe emi kún fun ọ̀rọ sisọ, ẹmi nrọ̀ mi ni inu mi.

Ka pipe ipin Job 32