Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 32:13-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Ki ẹnyin ki o má ba wipe, awa wá ọgbọ́n li awari: Ọlọrun li o lè bi i ṣubu, kì iṣe enia.

14. Bi on kò ti sọ̀rọ si mi, bẹ̃li emi kì yio fi ọ̀rọ nyin da a lohùn.

15. Ẹnu si yà wọn, nwọn kò si dahùn mọ́, nwọn ṣiwọ ọ̀rọ isọ.

16. Mo si reti, nitoriti nwọn kò si fọhùn, nwọn dakẹ jẹ, nwọn kò si dahùn mọ́.

17. Bẹ̃li emi o si dahùn nipa ti emi, emi pẹlu yio si fi ìmọ mi hàn.

18. Nitoripe emi kún fun ọ̀rọ sisọ, ẹmi nrọ̀ mi ni inu mi.

19. Kiyesi i, ikùn mi dabi ọti-waini, ti kò ni oju-iho; o mura tan lati bẹ́ bi igo-awọ titun.

20. Emi o sọ, ki ara ki o le rọ̀ mi, emi o ṣi ète mi, emi o si dahùn.

21. Lotitọ emi kì yio ṣe ojusaju enia, bẹ̃li emi kì yio si ṣe ipọnni fun ẹnikan.

22. Nitoripe emi kò mọ̀ ọ̀rọ ipọnni sọ, ni ṣiṣe bẹ̃ Ẹlẹda mi yio mu mi kuro lọgan.

Ka pipe ipin Job 32