Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 32:10-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Nitorina li emi ṣe wipe, ẹ dẹtisilẹ si mi, emi pẹlu yio fi ìmọ mi hàn.

11. Kiyesi i, emi ti duro de ọ̀rọ nyin, emi fetisi aroye nyin, nigbati ẹnyin nwá ọ̀rọ ti ẹnyin o sọ.

12. Ani mo fiyesi nyin tinutinu, si kiyesi i, kò si ẹnikan ninu nyin ti o le já Jobu li irọ́, tabi ti o lè ida a lohùn ọ̀rọ rẹ̀!

13. Ki ẹnyin ki o má ba wipe, awa wá ọgbọ́n li awari: Ọlọrun li o lè bi i ṣubu, kì iṣe enia.

14. Bi on kò ti sọ̀rọ si mi, bẹ̃li emi kì yio fi ọ̀rọ nyin da a lohùn.

15. Ẹnu si yà wọn, nwọn kò si dahùn mọ́, nwọn ṣiwọ ọ̀rọ isọ.

16. Mo si reti, nitoriti nwọn kò si fọhùn, nwọn dakẹ jẹ, nwọn kò si dahùn mọ́.

17. Bẹ̃li emi o si dahùn nipa ti emi, emi pẹlu yio si fi ìmọ mi hàn.

Ka pipe ipin Job 32