Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 30:5-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. A le wọn jade kuro lãrin enia, nwọn si ho le wọn bi ẹnipe si olè.

6. Lati gbé inu pàlapala okuta afonifoji, ninu iho ilẹ ati ti okuta.

7. Ninu igbẹ ni nwọn ndún, nwọn ko ara wọn jọ pọ̀ labẹ ẹgun neteli.

8. Awọn ọmọ ẹniti oye kò ye, ani ọmọ awọn enia lasan, a si le wọn kuro ninu ilẹ.

9. Njẹ nisisiyi emi di ẹni-orin fun wọn, ani emi di ẹni-asọrọsi fun wọn.

10. Nwọn korira mi, nwọn sa kuro jina si mi, nwọn kò si dá si lati tutọ́ si mi loju.

11. Nitoriti Ọlọrun ti tu okun-ìye mi, o si pọn mi loju; awọn pẹlu si dẹ̀ ijanu niwaju mi.

12. Awọn enia lasan dide li apa ọ̀tun mi, nwọn tì mi li ẹsẹ kuro, nwọn si là ipa-ọ̀na iparun silẹ dè mi.

13. Nwọn dà ipa-ọ̀na mi rú, nwọn ran jàmba mi lọwọ, awọn ti kò li oluranlọwọ;

14. Nwọn de si mi bi yiya omi gburu, ni ariwo nla ni nwọn ko ara wọn kátì si mi.

15. Ẹ̀ru nla yipada bà mi, nwọn lepa ọkàn mi bi ẹfùfù, alafia mi si kọja lọ bi awọsanma.

16. Ati nisisiyi ọkàn mi si dà jade si mi, ọjọ ipọnju dì mi mu.

17. Oru gùn mi ninu egungun mi, eyiti o bù mi jẹ kò si simi.

Ka pipe ipin Job 30