Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 30:23-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

23. Emi sa mọ̀ pe iwọ o mu mi lọ sinu ikú, ati si ile-apejọ fun gbogbo alãye.

24. Bi o ti wu ki o ṣe, ẹnikan kì yio ha nawọ rẹ̀ ni igba iṣubu rẹ̀, tabi kì yio ké ninu iparun rẹ̀.

25. Emi kò ha sọkun bi fun ẹniti o wà ninu iṣẹ, ọkàn mi kò ha bajẹ fun talaka bi?

26. Nigbati mo fojusọna fun alafia, ibi si de, nigbati emi duro de imọlẹ, òkunkun si de.

27. Ikùn mi nru, kò si simi, ọjọ ipọnju ti bá mi.

28. Emi nṣọ̀fọ lọ rinkiri laisi õrùn, emi dide duro ni awujọ, mo si kigbe.

29. Emi jasi arakunrin ajáko, emi di ẹgbẹ́ awọn abo-ogongo.

30. Àwọ mi di dudu li ara mi, egungun mi si jórun fun õru.

31. Dùru mi pẹlu si di ti ọ̀fọ, ati ohun-ọnà orin mi si di ohùn awọn ti nsọkún.

Ka pipe ipin Job 30