Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 30:12-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Awọn enia lasan dide li apa ọ̀tun mi, nwọn tì mi li ẹsẹ kuro, nwọn si là ipa-ọ̀na iparun silẹ dè mi.

13. Nwọn dà ipa-ọ̀na mi rú, nwọn ran jàmba mi lọwọ, awọn ti kò li oluranlọwọ;

14. Nwọn de si mi bi yiya omi gburu, ni ariwo nla ni nwọn ko ara wọn kátì si mi.

15. Ẹ̀ru nla yipada bà mi, nwọn lepa ọkàn mi bi ẹfùfù, alafia mi si kọja lọ bi awọsanma.

16. Ati nisisiyi ọkàn mi si dà jade si mi, ọjọ ipọnju dì mi mu.

17. Oru gùn mi ninu egungun mi, eyiti o bù mi jẹ kò si simi.

18. Nipa agbara nla aṣọ mi di pipada, o si lẹmọ́ mi li ara yika bi ọrùn aṣọ ileke mi.

Ka pipe ipin Job 30