Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 30:1-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ṢUGBỌN nisisiyi awọn ti mo gbà li aburo nfi mi ṣẹ̀sin, baba ẹniti emi kẹgàn lati tò pẹlu awọn ajá agbo-ẹran mi.

2. Pẹlupẹlu agbara ọwọ wọn kini o le igbè fun mi, awọn ẹniti kikún ọjọ wọn kò si.

3. Nitori aini ati ìyan nwọn di ẹni itakete, nwọn si girijẹ ohun jijẹ iju, ti o wà ni isọdahoro ati òfo lati lailai.

4. Awọn ẹniti njá ewe-iyọ li ẹ̀ba igbẹ, gbongbo igikigi li ohun jijẹ wọn.

5. A le wọn jade kuro lãrin enia, nwọn si ho le wọn bi ẹnipe si olè.

6. Lati gbé inu pàlapala okuta afonifoji, ninu iho ilẹ ati ti okuta.

7. Ninu igbẹ ni nwọn ndún, nwọn ko ara wọn jọ pọ̀ labẹ ẹgun neteli.

8. Awọn ọmọ ẹniti oye kò ye, ani ọmọ awọn enia lasan, a si le wọn kuro ninu ilẹ.

9. Njẹ nisisiyi emi di ẹni-orin fun wọn, ani emi di ẹni-asọrọsi fun wọn.

10. Nwọn korira mi, nwọn sa kuro jina si mi, nwọn kò si dá si lati tutọ́ si mi loju.

11. Nitoriti Ọlọrun ti tu okun-ìye mi, o si pọn mi loju; awọn pẹlu si dẹ̀ ijanu niwaju mi.

12. Awọn enia lasan dide li apa ọ̀tun mi, nwọn tì mi li ẹsẹ kuro, nwọn si là ipa-ọ̀na iparun silẹ dè mi.

13. Nwọn dà ipa-ọ̀na mi rú, nwọn ran jàmba mi lọwọ, awọn ti kò li oluranlọwọ;

14. Nwọn de si mi bi yiya omi gburu, ni ariwo nla ni nwọn ko ara wọn kátì si mi.

Ka pipe ipin Job 30